Matthew 19:13-15

Àwọn ọmọdé àti Jesu

13 aLẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí.

14Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run.” 15Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.

Copyright information for YorBMYO